ÈÈWỌ̀ GẸ́GẸ́ BÍ ADÁMỌLẸ́KUN ÌWÀ ÌDÀLÚRU

Authors

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.8284691

Keywords:

Èèwọ̀, ìwà ìdàlúrú, ìjọba, àṣà Yorùbá, ìjìyà

Abstract

Èèwọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé àwọn Yorùbá tí ó jẹyọ nínú àṣà, tí ó sì ṣe kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn èròjà àṣà tí àwùjọ Yorùbá ń lò fún òfin èyí tí a fi ń ṣe ètò ìlú lọ́nà tí ó ń mú kí àwọn ará ìlú kó ara wọn ní ìjánu àti yàgò fún ohun tí kò wọ̀. Bí ìlú ṣe rí lóde òní kò sàìjẹ́ kí á bèèrè pé 'ṣé báyìí ni ojú rí tí wọ́n fi ń jobì lọ́jà Ẹdẹ?'. Ohun tó ṣokùnfà ìbéèrè yìí ni pé, kò sí ibi tí ìfọ̀kànbalẹ̀ àti àbò tó péye wà mọ́ ní àwùjọ òní nítorí ìwà ìdàlúrú àti ìpànìyàn tó gb'òde kan èyí tí kò wọ́pọ̀ ní ayé àtijọ́ nítorí àwọn ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tí àwon babańlá wa ń gbà ṣe ètò ìlú. Ìyànjú láti wo bí àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wa bíi èèwọ̀ ṣe lè dẹ́kun rògbòdìyàn tàbí ìwà ìdàlúrú tí ó ń peléke síi ní orílẹ̀-èdè yìí ni ó ṣokùnfà bébà yìí. Iṣẹ́ ìwádìí yìí tú'ṣu dé ìsàlẹ̀ ikoko lórí bí èèwọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀, ohun tí èèwọ̀ jẹ́, ìdẹ́jàá èèwọ̀, ìbẹ̀rẹ̀ ìwà ìdàlúrú, ohun tí ó ń ṣokùnfà ìwà ìdàlúrú àti bí èèwọ̀ ṣe lè dẹ́kun ìwà ìdàlúrú.

Downloads

Published

2023-08-26

How to Cite

Dayo , A. (2023). ÈÈWỌ̀ GẸ́GẸ́ BÍ ADÁMỌLẸ́KUN ÌWÀ ÌDÀLÚRU. Journal of College of Languages and Communication Arts Education, 1(1), 199–207. https://doi.org/10.5281/zenodo.8284691