ÀGBÉYẸ̀WÒ ỌNÀ-ÈDÈ INÚ ORIN ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ: ORIN SÁKÁRÀ ÒSÉNÌ ÈJÌRẸ́ GẸ́GẸ́ BÍ ÀWÒTA

Authors

  • Rifqat Opeyemi SANNI Department of Nigerian Languages, College of Languages and Communication Arts Education, Lagos State University of Education, Oto/Ijanikin, Lagos. https://orcid.org/0000-0002-4715-8580
  • Samuel Oludayo AKANMU Department of Nigerian Languages, College of Languages and Communication Arts Education, Lagos State University of Education, Oto/Ijanikin, Lagos. https://orcid.org/0000-0002-4715-8580

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.8321240

Keywords:

orin ìbílẹ̀, orin sákárà, ọnà-èdè, ìpàkíyèsí, tíọ́rì ìfojú-ìhun-wo

Abstract

Ọ̀kan-ò-jọ̀kan iṣẹ́ ló ti wà nílẹ̀ lórí orín ìbílẹ Yorùbá àti ìlò-èdè, ṣùgbọ́n a kò tí ì rí ẹni ṣiṣẹ́ lórí ọnà-èdè inú orin sákárà Òsénì Èjìrẹ́. Èyí ló mú kí a yàn láti tanná wo àwọn ọnà-èdè tí olórin yìí fi ṣẹwà sí èrò àti kókó-ọ̀rọ̀ tó gbé kalẹ̀ nínú àwọn àwo orin sákárà mẹ́rin. Ṣíṣe àbẹ̀wò sílé Òsénì Èjìrẹ́ láti lè rí ọmọ rẹ̀ tí ó ṣì ń kọ orin sákárà ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. Èyí jẹ́ kí a ní ànfààní sí ọ̀pọ̀ nínú àwọn àwo orin tí olorin yìí kọ nígbà ayé rẹ̀. Àṣàyàn àti àdàkọ àwọn àwo orin tí a kíyèsí pé ẹ̀dọ̀ki èdè ṣarajọ sínú wọn ni ìgbésẹ̀ mìíràn tí a gbé nínú iṣẹ́ yìí. Àwọn àwo orin tí a yàn náà ni Mójú Kúrò, Ayé ń yí lọ, Ìtàn Àwórì àti Ìrírí Ayé. Àkànlò èdè ayàwòrán tí ó ṣodo sínú àwo orin mẹ́rin yìí ni ó ṣokùnfà àṣàyàn wọn nínú gbogbo àwo orin tí Òsénì Èjìrẹ́ ṣe. Abala Roman Jakobson (1960) àti Riffatterre (1979) lórí tíọ́rì ìfojú-ìhun-wo iṣẹ́-ọnà ni a yàn láàyò fún ìtúpalẹ̀ pépà yìí nítorí pé òun ni a ṣe àkíyèsí pé ó pegede láti fi ṣe àtúpalẹ̀ irú iṣẹ́ ọnà tí àkànlò èdè ayàwòrán ṣodo sínú rẹ̀ báyìí. Òsénì Èjìrẹ́ lò àkànlò èdè aayàwòrán bíi àwítúnwí àti àwọn mìíràn láti pe àkíyèsí àwùjọ sí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ tó jẹ ẹ́ lọ́kàn àtii láti fún afọ̀ ní ìtumọ̀ tó jinlẹ̀, tó sì mú ni lọ́kàn. Òsénì Èjìrẹ́ kò sàìlo àwọn àkànlò-èdè ayàwòrán wọ̀nyí ní ìbámu pẹ̀lú ìlò wọn láwùjọ Yorùbá. Èyí jẹ́ kí á lè sọ ní pàtó pé agbédè-gbẹ́yọ̀ ni Òsénì Èjìrẹ́, bẹ́ẹ̀ kì í ṣe alóyin lóhùn lásán.

COVER

Downloads

Published

2023-09-07

How to Cite

SANNI , R. O., & AKANMU , S. O. (2023). ÀGBÉYẸ̀WÒ ỌNÀ-ÈDÈ INÚ ORIN ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ: ORIN SÁKÁRÀ ÒSÉNÌ ÈJÌRẸ́ GẸ́GẸ́ BÍ ÀWÒTA. Journal of College of Languages and Communication Arts Education , 2(1), 148–163. https://doi.org/10.5281/zenodo.8321240