Fífi Ojú Ìmọ̀ síńtáàsì Ṣe Àtúpalẹ̀ Arọ́pò-orúkọ Ní Ipò Olùwà Nínú Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú-Ẹ̀pẹ́

Authors

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.8277988

Keywords:

Arọ́pò-orúkọ, Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá, Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ atẹ́rẹrẹ, Ìyísódì

Abstract

Ohun pàtàkì tí iṣẹ́ yìí dá lé lórí ni fífi ojú ìmọ̀ síńtáàsì ṣe àtúpalẹ̀ arọ́pò-orúkọ ní ipò olùwà nínú ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú-Ẹ̀pẹ́, èyí tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ẹ̀ka-èdè Yorùbá tí wọ́n ń sọ ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Iṣẹ́ yìí ṣe àkíyèsí arọ́pò-orúkọ nínú ìhun gbólóhùn ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú-Ẹ̀pẹ́. Bákan náà, iṣẹ́ yìí fi ìjọra àti ìyàtọ̀ tó wà láàrín arọ́pò-orúkọ nínú ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú-Ẹ̀pẹ́ àti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá hàn nípa lílo Tíọ́rì Gírámà Ìhun Alákòótán (Generalised Phrase Structure Grammar) tí Cann (1986) ṣe agbátẹrù rẹ̀. Pépà yìí fihàn pé olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá àti ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú-Ẹ̀pẹ́ ní ọ̀nà àti ìlànà tí wọ́n ń gbà ṣe àmúlò arọ́pò-orúkọ nínú èyí tí yóò tún la ojú òpó ìmọ̀ nípa ẹ̀ka-èdè sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń bọ̀.

Downloads

Published

2023-08-24

How to Cite

Alimi , P. O., & Olabode , O. T. (2023). Fífi Ojú Ìmọ̀ síńtáàsì Ṣe Àtúpalẹ̀ Arọ́pò-orúkọ Ní Ipò Olùwà Nínú Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú-Ẹ̀pẹ́ . Journal of College of Languages and Communication Arts Education, 1(1), 26–47. https://doi.org/10.5281/zenodo.8277988