ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌṢÀMÚLÒ EWÉ ÀTI EGBÒ ÌBÍLẸ̀ GẸ́GẸ́ BÍ Ọ̀NÀ ÀBÁYỌ SÍ ÌPÈNÍJÀ ÀÌLERA

Authors

  • E. ỌLANIKẸ ADÉKỌ̀YÀ Department of Nigerian Languages, College of Languages and Communication Arts Education. Lagos State University of Education, Oto/Ijanikin Lagos with Campus at Epe. https://orcid.org/0000-0002-4715-8580

DOI:

https://doi.org/10.5281/zenodo.8324887

Keywords:

Àìlera, ewé àti egbò ìbílẹ̀, ìpèníjà, ìṣàmúlò, ọ̀nà àbáyọ

Abstract

Ètò ìlera jẹ́ kòséémàní fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn, èyí kò sì yọ ẹ̀yà Yorùbá sílẹ̀ rárá. Ipò tí ètò ìlera wà fún gbogbo ènìyàn láti bi ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láì sí ọ̀nà àbáyọ kan gbòógì láti ọ̀dọ̀ ìjọba fihàn pé ètò ìlera tolórí-tẹlẹ́mù ti mẹ́hẹ. Èyí ló gún olùwádìí ní kẹ́ṣẹ́ àgbéyẹ̀wò ọ̀nà àbáyọ tí àwọn ènìyàn ń lò láti wá ojútùú sí àwọn ìpèníjà àìlera tó ń ba ẹ̀dá fí́nra.  Àfojúsùn iṣẹ́ yìí ni láti ṣe àgbéyẹ̀wò oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn ń gbà láti wá ojútùú sí àwọn ìpèníjà àìlera wọ̀nyí. Ọ̀nà ìwádìí iṣẹ́ yìí jẹ mọ́ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, àgbéyẹ̀wò àsọdàsílẹ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n bíi Orímóògùnjẹ́ (2015), Agbájé ninu Ilesanmi (1989) àti àwọn mìíràn tó ti ṣiṣẹ́ lórí iṣẹ́ ìṣègùn ìbílẹ̀ àti ìlera, pẹ̀lú wíwo àwọn ohun tó lè jẹ́ ojútùú àrọ́wọ́tó sí ìpèníjà àìlera fún mùtúmùwà. Tíọ́rì ìfojú-àṣà-ìbílẹ̀-wò ti Abímbọ́lá (1982) ni a ó fi ṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí nítorí pé àfojúsùn iṣẹ́ yìí dúró lórí àfihàn oríṣìíríṣìí ìtagbọ́n-inú tí àwọn ẹ̀dá ń ṣe àmúlò láti wá ojútùú sí ìṣòrokíṣòro tó bá dé bá wọn pàápàá jùlọ èyí tó bá la ìlera lọ. Àbájáde iṣẹ́ yìí fi hàn pé látàrí àìní àti àìtó, àwọn ènìyàn ń tiraka ní ìlànà ìbílẹ̀ láti wá ọ̀nà àbáyọ àti ojútùú sí gbogbo ìpèníjà àìlera tó ń bá wọn fí́nra wọ̀nyí. Ó sì pọn dandan kí ìgbésẹ̀ tí ó tọ̀nà jẹ́ atọ́kùn sí ìlànà wọ̀nyí.

 

COVER

Downloads

Published

2023-09-07

How to Cite

ADÉKỌ̀YÀ E. O. (2023). ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌṢÀMÚLÒ EWÉ ÀTI EGBÒ ÌBÍLẸ̀ GẸ́GẸ́ BÍ Ọ̀NÀ ÀBÁYỌ SÍ ÌPÈNÍJÀ ÀÌLERA. Journal of College of Languages and Communication Arts Education , 2(1), 175–185. https://doi.org/10.5281/zenodo.8324887